Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 9:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Gbogbo wọn ni wọ́n ń wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un. Fún ọpọlọpọ ọdún ni

24. ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn máa ń mú ẹ̀bùn wá fún un lọdọọdun, àwọn ẹ̀bùn bíi: ohun èlò fadaka, ati ti wúrà, aṣọ, ohun ìjà ogun, turari, ẹṣin, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

25. Solomoni ọba ní ẹgbaaji (4,000) ilé fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, ó ní ẹgbaafa (12,000) ẹlẹ́ṣin. Ó kó àwọn kan sí àwọn ìlú tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ó kó ìyókù sí Jerusalẹmu, níbi tí ọba ń gbé.

26. Solomoni jọba lórí àwọn ọba gbogbo, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati títí dé ààlà Ijipti.

27. Ní àkókò tirẹ̀, ó mú kí fadaka pọ̀ bí òkúta ní Jerusalẹmu, igi kedari sì pọ̀ bíi igi sikamore tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè Juda.

28. A máa ra ẹṣin wá láti Ijipti ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.

29. Gbogbo ìtàn ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn wolii Natani, ati ninu ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Ahija ará Ṣilo, ati ninu ìwé ìran tí Ido rí nípa Jeroboamu ọba Israẹli, ọmọ Nebati.

30. Solomoni jọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli fún ogoji ọdún.

31. Ó kú, a sì sin ín sí ìlú Dafidi, baba rẹ̀. Rehoboamu, ọmọ rẹ̀, ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 9