Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 7:13-21 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi,

14. bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn.

15. Nisinsinyii, n óo fojú sílẹ̀, etí mi yóo sì ṣí sí adura tí wọ́n bá gbà níbí yìí.

16. Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.

17. Ṣugbọn, bí ìwọ bá tẹ̀lé ìlànà mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o tẹ̀lé ìlànà ati àṣẹ mi,

18. n óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀, bí mo ti bá Dafidi, baba rẹ, dá majẹmu pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli.

19. Ṣugbọn tí o bá yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí o kọ àṣẹ mi ati òfin tí mo ṣe fún ọ sílẹ̀, tí o sì ń lọ bọ oriṣa, tí ò ń foríbalẹ̀ fún wọn,

20. n óo fà yín tu kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fun yín bí ẹni fa igi tu. N óo sì kọ tẹmpili yìí, tí mo ti yà sí mímọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi sílẹ̀, nítorí pé yóo di ohun ẹ̀gàn ati àmúpòwe láàrin gbogbo eniyan.

21. “Tẹmpili yìí gbayì gidigidi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà náà, àwọn ẹni tó bá ń rékọjá lọ yóo máa sọ tìyanu-tìyanu pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati sí tẹmpili yìí?’

Ka pipe ipin Kronika Keji 7