Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 7:10-13 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ní ọjọ́ kẹtalelogun oṣù keje, Solomoni ní kí àwọn eniyan máa pada lọ sílé wọn. Inú wọn dùn nítorí ohun rere tí OLUWA ṣe fún Dafidi, ati Solomoni ati gbogbo Israẹli.

11. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sí ilé OLUWA ati sí ilé ti ara rẹ̀, ni ó ṣe ní àṣeyọrí.

12. Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi.

13. Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi,

Ka pipe ipin Kronika Keji 7