Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà.