Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 33:17-22 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Sibẹsibẹ àwọn eniyan ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi ìrúbọ, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun wọn ni wọ́n ń rúbọ sí.

18. Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Manase ṣe, ati adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati àwọn ọ̀rọ̀ tí aríran sọ fún un ní orúkọ OLUWA, Ọlọrun Israẹli, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Israẹli.

19. Adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati bí Ọlọrun ṣe dá a lóhùn, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ati aiṣododo rẹ̀, wà ninu ìwé Ìtàn Àwọn Aríran. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ibi tí ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ sí, àwọn ère tí ó gbẹ́ fún Aṣera, ati àwọn ère tí ó ń sìn kí ó tó ronupiwada.

20. Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ààfin rẹ̀. Amoni, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

21. Ọmọ ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji ní Jerusalẹmu.

22. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bíi Manase, baba rẹ̀, ó rúbọ sí gbogbo oriṣa tí baba rẹ̀ ṣe, ó sì ń bọ wọ́n.

Ka pipe ipin Kronika Keji 33