Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 33:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Nígbà tí ó wà ninu ìpọ́njú ó wá ojurere OLUWA Ọlọrun, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ patapata níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀.

13. Ó gbadura sí OLUWA, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, ó sì mú un pada wá sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ó wá mọ̀ nígbà náà pé OLUWA ni Ọlọrun.

14. Lẹ́yìn náà ó mọ odi ìta sí ìlú Dafidi, ní apá ìwọ̀ oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, ati sí ẹnubodè ẹja; ó mọ ọ́n tí ó ga yípo Ofeli. Ó kó àwọn ọ̀gágun sinu àwọn ìlú olódi ní Juda.

15. Ó kó àwọn oriṣa ati àwọn ère kúrò ninu ilé OLUWA, ati gbogbo ojúbọ oriṣa tí ó kọ́ sórí òkè níbi tí ilé OLUWA wà, ati àwọn tí wọ́n kọ́ káàkiri gbogbo ìlú Jerusalẹmu. Ó da gbogbo wọn sẹ́yìn odi ìlú.

16. Ó tún pẹpẹ OLUWA tẹ́ sí ipò rẹ̀, ó rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ọpẹ́ lórí rẹ̀, ó sì pàṣẹ fún àwọn eniyan Juda pé kí wọ́n máa sin OLUWA Ọlọrun Israẹli.

17. Sibẹsibẹ àwọn eniyan ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi ìrúbọ, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun wọn ni wọ́n ń rúbọ sí.

Ka pipe ipin Kronika Keji 33