Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 32:2-11 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Nígbà tí Hesekaya rí i pé Senakeribu ti pinnu láti gbógun ti Jerusalẹmu,

3. ó jíròrò pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ bí wọn yóo ti ṣe dí ìṣàn omi tí ó wà lẹ́yìn odi ìlú; wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

4. Wọ́n kó ọpọlọpọ eniyan jọ, wọ́n dí àwọn orísun omi ati àwọn odò tí ń ṣàn ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ní, “Kò yẹ kí ọba Asiria wá, kí ó bá omi tí ó tó báyìí.”

5. Ọba yan àwọn òṣìṣẹ́ láti mọ gbogbo àwọn odi tí ó wó lulẹ̀, ati láti kọ́ ilé ìṣọ́ sí orí wọn. Wọ́n tún mọ odi mìíràn yípo wọn. Ó tún Milo tí ó wà ní ìlú Dafidi ṣe kí ó fi lágbára síi, ó sì pèsè ọpọlọpọ nǹkan ìjà ati apata.

6. Ọba yan àwọn ọ̀gágun lórí àwọn eniyan, ó sì pe gbogbo wọn jọ sí gbàgede ẹnubodè ìlú. Ó dá wọn lọ́kàn le, ó ní,

7. “Ẹ múra, ẹ ṣọkàn gírí. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà níwájú ọba Asiria ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀; nítorí agbára ẹni tí ó wà pẹlu wa ju ti àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ lọ.

8. Agbára ti ẹran ara ni àwọn ọmọ ogun tirẹ̀ ní, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun ni ó wà pẹlu wa láti ràn wá lọ́wọ́ ati láti jà fún wa.” Ọ̀rọ̀ tí Hesekaya ọba Juda sọ sì fi àwọn eniyan rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀.

9. Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Senakeribu ati àwọn ogun rẹ̀ gbógun ti Lakiṣi, ó ranṣẹ sí Hesekaya ọba Juda ati àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu pé,

10. “Òun Senakeribu, ọba Asiria ní, kí ni wọ́n gbójú lé tí wọ́n fi dúró sí Jerusalẹmu, ìlú tí ogun dó tì?

11. Ó ní bí Hesekaya bá ní OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n lọ́wọ́ òun ọba Asiria, ó ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, ó fẹ́ kí òùngbẹ ati ebi pa wọ́n kú ni.

Ka pipe ipin Kronika Keji 32