Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 3:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó yọ́ wúrà bo gbogbo igi àjà ilé náà patapata, ati àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ògiri rẹ̀ ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fi àwòrán àwọn kerubu dárà sí ara àwọn ògiri.

8. Ó kọ́ ibi mímọ́ jùlọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé ìbú tẹmpili náà, ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9). Ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó yọ́ ìwọ̀n ẹgbẹta (600) talẹnti ojúlówó wúrà, ó fi bo gbogbo inú rẹ̀.

9. Aadọta ìwọ̀n ṣekeli wúrà ni ó fi ṣe ìṣó, ó sì yọ́ wúrà bo gbogbo ara ògiri yàrá òkè.

10. Ó fi igi gbẹ́ kerubu meji, ó yọ́ wúrà bò wọ́n, ó sì gbé wọn sí ibi mímọ́ jùlọ.

11. Gígùn gbogbo ìyẹ́ kerubu mejeeji jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni keji jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ kerubu kinni nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìyẹ́ rẹ̀ keji tí òun náà jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), nà kan ìyẹ́ kerubu keji.

12. Ekinni ninu àwọn ìyẹ́ kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, ó nà kan ògiri ilé náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji, ìyẹ́ rẹ̀ keji náà jẹ́ igbọnwọ marun-un, òun náà nà kan ìyẹ́ ti kerubu kinni.

13. Àwọn kerubu yìí dúró, wọ́n kọjú sí gbọ̀ngàn ilé náà; gígùn gbogbo ìyẹ́ wọn jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9).

Ka pipe ipin Kronika Keji 3