Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 3:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ó ṣe òpó meji sí iwájú ilé náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ga ní igbọnwọ marundinlogoji (mita 15). Ọpọ́n orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ga ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un (mita 2¼).

16. Ó ṣe àwọn nǹkankan bí ẹ̀wọ̀n, ó fi wọ́n sórí àwọn òpó náà. Ó sì ṣe ọgọrun-un (100) èso pomegiranate, ó so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà.

17. Ó gbé àwọn òpó náà kalẹ̀ níwájú tẹmpili, ọ̀kan ní ìhà àríwá, wọ́n ń pè é ní Jakini, ekeji ní ìhà gúsù, wọ́n ń pè é ní Boasi.

Ka pipe ipin Kronika Keji 3