Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 28:25-27 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ó ṣe ibi ìrúbọ káàkiri àwọn ìlú Juda níbi tí yóo ti máa sun turari sí àwọn oriṣa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó mú OLUWA Ọlọrun àwọn baba rẹ̀ bínú.

26. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasi ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati ti Israẹli.

27. Nígbà tí Ahasi ọba kú, wọ́n sin ín sí Jerusalẹmu, wọn kò sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba. Hesekaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Kronika Keji 28