Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 28:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣugbọn ó ṣe bí àwọn ọba Israẹli, ó tilẹ̀ yá ère fún oriṣa Baali.

3. Ó ń sun turari ní àfonífojì àwọn ọmọ Hinomu, ó sì ń fi àwọn ọmọkunrin rẹ̀ rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú Israẹli ń hù.

4. Ó rúbọ, ó sun turari ní àwọn ibi ìrúbọ, ati lórí òkè káàkiri ati lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5. Nítorí náà OLUWA Ọlọrun rẹ̀ fi í lé ọba Siria lọ́wọ́. Ọba Siria ṣẹgun rẹ̀, ó sì kó àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́rú lọ sí Damasku. Ọlọrun tún fi lé ọba Israẹli lọ́wọ́, ó ṣẹgun rẹ̀, ó sì pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní ìpakúpa.

6. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, Peka, ọmọ Remalaya, ọba Israẹli, pa ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ninu àwọn ọmọ ogun Juda; tí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni. Ọlọrun jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀.

7. Sikiri, akikanju jagunjagun kan, ará Efuraimu pa Maaseaya, ọmọ ọba, ati Asirikamu, olórí ogun tí ń ṣọ́ ààfin ọba, ati Elikana, igbákejì ọba.

8. Àwọn tí ará ilẹ̀ Israẹli dè ní ìgbèkùn lọ ninu àwọn ará ilé Juda jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àtàwọn obinrin, àtàwọn ọmọkunrin, àtàwọn ọmọbinrin; wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun lọ sí Samaria.

9. Wolii OLUWA kan tí ń jẹ́ Odedi wà ní ìlú Samaria; ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Israẹli nígbà tí wọ́n ń pada bọ̀. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín bínú sí àwọn ará Juda ni ó fi jẹ́ kí ẹ ṣẹgun wọn, ṣugbọn ẹ pa wọ́n ní ìpakúpa tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun pàápàá ṣàkíyèsí rẹ̀.

10. Ẹ tún wá fẹ́ kó tọkunrin tobinrin Juda ati Jerusalẹmu lẹ́rú. Ṣé ẹ̀yin alára náà kò ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun yín?

11. Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ dá àwọn arakunrin yín tí ẹ ti kó lẹ́rú pada, nítorí ibinu OLUWA wà lórí yín.”

12. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè kan lára àwọn ará Efuraimu: Asaraya, ọmọ Johanani, Berekaya, ọmọ Meṣilemoti, Jehisikaya, ọmọ Ṣalumu ati Amasa, ọmọ Hadilai dìde, wọ́n tako àwọn tí ń ti ojú ogun bọ̀, wọ́n sọ fún wọn pé,

Ka pipe ipin Kronika Keji 28