Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 28:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀.

2. Ṣugbọn ó ṣe bí àwọn ọba Israẹli, ó tilẹ̀ yá ère fún oriṣa Baali.

3. Ó ń sun turari ní àfonífojì àwọn ọmọ Hinomu, ó sì ń fi àwọn ọmọkunrin rẹ̀ rú ẹbọ sísun, gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú Israẹli ń hù.

4. Ó rúbọ, ó sun turari ní àwọn ibi ìrúbọ, ati lórí òkè káàkiri ati lábẹ́ gbogbo igi tútù.

5. Nítorí náà OLUWA Ọlọrun rẹ̀ fi í lé ọba Siria lọ́wọ́. Ọba Siria ṣẹgun rẹ̀, ó sì kó àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́rú lọ sí Damasku. Ọlọrun tún fi lé ọba Israẹli lọ́wọ́, ó ṣẹgun rẹ̀, ó sì pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní ìpakúpa.

6. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, Peka, ọmọ Remalaya, ọba Israẹli, pa ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) ninu àwọn ọmọ ogun Juda; tí gbogbo wọn sì jẹ́ akọni. Ọlọrun jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀.

7. Sikiri, akikanju jagunjagun kan, ará Efuraimu pa Maaseaya, ọmọ ọba, ati Asirikamu, olórí ogun tí ń ṣọ́ ààfin ọba, ati Elikana, igbákejì ọba.

Ka pipe ipin Kronika Keji 28