Bí ọdún náà ti ń dópin lọ, àwọn ọmọ ogun Siria gbógun ti Joaṣi. Nígbà tí wọ́n dé Juda ati Jerusalẹmu, wọ́n pa gbogbo àwọn ìjòyè wọn, wọ́n sì kó gbogbo ìkógun wọn ranṣẹ sí Damasku.