Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 2:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Solomoni ọba pinnu láti kọ́ tẹmpili níbi tí àwọn eniyan yóo ti máa sin OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.

2. Ó kó ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000) àwọn òṣìṣẹ́ jọ láti máa ru àwọn nǹkan tí yóo fi kọ́lé, ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) àwọn òṣìṣẹ́ tí yóo máa fọ́ òkúta, ati ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) eniyan láti máa bojútó àwọn òṣìṣẹ́.

3. Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀.

4. Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae.

5. Ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi pupọ, nítorí pé Ọlọrun wa tóbi ju gbogbo oriṣa lọ.

6. Kò sí ẹni tí ó lè kọ́ ilé fún un, nítorí pé ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò le è gbà á. Kí ni mo jẹ́ tí n óo fi kọ́ ilé fún un, bíkòṣe pé kí n kọ́ ibi tí a óo ti máa sun turari níwájú rẹ̀?

Ka pipe ipin Kronika Keji 2