Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 18:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.”Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.”

8. Nítorí náà, Ahabu ọba pe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ kí ó lọ pe Mikaya wá kíákíá.

9. Àwọn ọba mejeeji gúnwà lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà, ní àbáwọ bodè Samaria, gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

10. Ọ̀kan ninu àwọn wolii tí à ń pè ní Sedekaya, ọmọ Kenaana ṣe àwọn ìwo irin kan, ó sì sọ fún Ahabu pé, “OLUWA ní, pẹlu àwọn ìwo wọnyi ni o óo fi bi àwọn ará Siria sẹ́yìn, títí tí o óo fi run wọ́n patapata.”

11. Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.”

12. Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.”

13. Ṣugbọn Mikaya dáhùn pé, “Mo fi orúkọ OLUWA búra pé ohun tí Ọlọrun bá sọ fún mi pé kí n sọ ni n óo sọ.”

14. Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?”Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.”

15. Ṣugbọn Ahabu bi í pé, “Ìgbà mélòó ni mo níláti mú ọ búra pé kí o máa sọ òtítọ́ fún mi ní orúkọ OLUWA?”

16. Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ”

17. Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣé o ranti pé mo ti sọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún mi rí? Àsọtẹ́lẹ̀ burúkú nìkan ni òun máa ń sọ.”

Ka pipe ipin Kronika Keji 18