Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 17:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ṣugbọn ó ń sin Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, ó pa òfin Ọlọrun mọ́, kò sì tẹ̀lé ìṣe àwọn ọmọ Israẹli.

5. Nítorí náà OLUWA fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Juda sì ń san owó orí fún un. Nítorí náà ó di ọlọ́rọ̀ ati ọlọ́lá.

6. Ó fi ìgboyà rìn ní ọ̀nà OLUWA, ó wó gbogbo pẹpẹ oriṣa, ó sì gé àwọn ère Aṣera káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda.

7. Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó pe àwọn marun-un ninu àwọn ìjòyè rẹ̀: Benhaili, Ọbadaya, ati Sakaraya, Netaneli, ati Mikaya, ó rán wọn jáde láti máa kọ́ àwọn eniyan ní ilẹ̀ Juda.

8. Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wọn lọ ni: Ṣemaaya, Netanaya, ati Sebadaya; Asaheli, Ṣemiramotu, ati Jehonatani; Adonija, Tobija ati Tobadonija. Àwọn alufaa tí wọ́n tẹ̀lé wọn ni Eliṣama ati Jehoramu.

9. Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda pẹlu ìwé òfin lọ́wọ́ wọn, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan.

10. OLUWA da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí Juda ká, wọn kò sì gbógun ti Jehoṣafati.

11. Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá.

Ka pipe ipin Kronika Keji 17