Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali.