Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 15:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Orílẹ̀-èdè kan ń pa ekeji run, ìlú kan sì ń pa ekeji rẹ́, nítorí Ọlọrun mú oniruuru ìpọ́njú bá wọn.

7. Ṣugbọn, ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ mọ́kàn le, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó rẹ̀ yín, nítorí iṣẹ́ yín yóo ní èrè.”

8. Nígbà tí Asa gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Asaraya ọmọ Odedi sọ, ó mọ́kàn le. Ó kó gbogbo ère kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini ati ní gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n gbà ní agbègbè olókè Efuraimu. Ó tún pẹpẹ OLUWA tí ó wà níwájú yàrá àbáwọlé ilé OLUWA ṣe.

9. Ó kó gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Bẹnjamini jọ, ati àwọn tí wọ́n wá láti Efuraimu, Manase ati Simeoni, tí wọ́n jẹ́ àlejò láàrin wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ eniyan láti ilẹ̀ Israẹli ni wọ́n ti sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.

10. Wọ́n péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹẹdogun ìjọba Asa.

11. Wọ́n mú ẹẹdẹgbẹrin (700) mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan ninu ìkógun tí wọ́n kó, wọ́n fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.

12. Wọ́n dá majẹmu pé àwọn yóo máa sin OLUWA Ọlọrun baba àwọn tọkàntọkàn àwọn;

13. ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, ìbáà ṣe àgbà tabi ọmọde, ọkunrin tabi obinrin, pípa ni àwọn yóo pa á.

14. Wọ́n fi igbe búra ní orúkọ OLUWA pẹlu ariwo ati fèrè.

15. Inú gbogbo Juda sì dùn sí ẹ̀jẹ́ náà, nítorí pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi jẹ́ ẹ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń sin Ọlọrun. Ọlọrun gba ìsìn wọn, ó sì fún wọn ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.

Ka pipe ipin Kronika Keji 15