Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 12:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu.

8. Sibẹsibẹ wọn yóo jẹ́ ẹrú rẹ̀, kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ ninu pé kí wọ́n sin òun OLUWA, ati kí wọ́n sin ìjọba àwọn ilẹ̀ mìíràn.

9. Ṣiṣaki bá gbógun ti Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ìṣúra ilé OLUWA lọ, ati ti ààfin ọba patapata, ati apata wúrà tí Solomoni ṣe.

10. Nítorí náà, Rehoboamu ṣe apata bàbà dípò wọn, ó sì fi wọ́n sábẹ́ àkóso olùṣọ́ ààfin.

11. Nígbàkúùgbà tí ọba bá lọ sí ilé OLUWA, olùṣọ́ ààfin á ru apata náà ní iwájú rẹ̀, lẹ́yìn náà yóo kó wọn pada sí ibi tí wọ́n kó wọn pamọ́ sí.

12. Nítorí pé Rehoboamu ronupiwada, OLUWA yí ibinu rẹ̀ pada, kò pa á run patapata mọ́. Nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ dáradára ní ilẹ̀ Juda.

Ka pipe ipin Kronika Keji 12