Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun.