Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 1:3-7 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Solomoni ati àwọn tí wọ́n péjọ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gibeoni, nítorí pé àgọ́ ìpàdé Ọlọrun tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa ninu aginjù wà níbẹ̀.

4. Ṣugbọn Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọrun wá láti Kiriati Jearimu sinu àgọ́ tí ó pa fún un ní Jerusalẹmu.

5. Pẹpẹ bàbà tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri ṣe, wà níbẹ̀ níwájú àgọ́ OLUWA. Solomoni ati àwọn eniyan rẹ̀ sin OLUWA níbẹ̀.

6. Ó lọ sí ìdí pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA ninu àgọ́ àjọ, ó sì fi ẹgbẹrun (1,000) ẹran rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀.

7. Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun fara han Solomoni, ó wí fún un pé “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́ kí n fún ọ.”

Ka pipe ipin Kronika Keji 1