Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 6:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi Jẹriko ninu ati lóde, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnikẹ́ni kò lè jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè wọlé.

2. OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn.

3. Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa.

4. Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn.

5. Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.”

6. Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.”

7. Ó sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa tẹ̀síwájú, ẹ rìn yípo ìlú náà kí àwọn ọmọ ogun ṣáájú Àpótí Majẹmu OLUWA.”

8. Gẹ́gẹ́ bí Joṣua ti pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, àwọn alufaa meje mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú OLUWA, wọ́n ṣáájú, wọ́n ń fọn fèrè ogun wọn; àwọn tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sì tẹ̀lé wọn.

9. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́.

Ka pipe ipin Joṣua 6