Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 5:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Nígbà náà ni OLUWA wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ, kí o sì fi kọ ilà abẹ́ lẹẹkeji fún àwọn ọmọ Israẹli.”

3. Joṣua bá fi akọ òkúta ṣe abẹ, ó fi kọ ilà abẹ́ fún gbogbo ọkunrin Israẹli ní Gibeati Haaraloti.

4. Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n kọ ilà abẹ́, ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bí lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ilẹ̀ Ijipti kò kọ ilà.

6. Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.

Ka pipe ipin Joṣua 5