Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 22:20-32 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ṣebí ìwà ọ̀dàlẹ̀ báyìí náà ni Akani ọmọ Sera hù nígbà tí ó kọ̀, tí kò tẹ̀lé àṣẹ tí OLUWA pa nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ OLUWA, ṣebí gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli ni OLUWA bínú sí? Àbí òun nìkan ni ó ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?”

21. Ni àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase bá dá àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli lóhùn pé,

22. “Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA! Ọlọrun Alágbára, Ọlọrun ni OLUWA, ó mọ ìdí tí a fi ṣe ohun tí a ṣe, a sì fẹ́ kí ẹ̀yin ọmọ Israẹli náà mọ̀ pẹlu. Tí ó bá jẹ́ pé oríkunkun ati ìwà ọ̀dàlẹ̀ ni a fẹ́ hù sí OLUWA ni a fi ṣe ohun tí a ṣe, ẹ má ṣàánú wa.

23. Bí ó bá jẹ́ pé a tẹ́ pẹpẹ tí yóo mú wa kọ OLUWA sílẹ̀, tabi pé a tẹ́ pẹpẹ fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ alaafia, kí OLUWA gbẹ̀san lára wa.

24. Ká má rí i! Ohun tí ó mú wa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rù ń bà wá pé, nígbà tí ó bá di ọjọ́ iwájú, àwọn ọmọ yín lè wí fún àwọn ọmọ wa pé, ‘Ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli kò kàn yín.

25. Nítorí OLUWA ti fi odò Jọdani ṣe ààlà láàrin àwa pẹlu yín, ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’ Àwọn ọmọ yín sì lè mú kí àwọn ọmọ wa má sin OLUWA mọ́.

26. Nítorí náà, ni a ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á tẹ́ pẹpẹ kan,’ kì í ṣe fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ mìíràn,

27. ṣugbọn yóo wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, láàrin àwa pẹlu yín, ati àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn wa, pé àwa náà yóo máa sin OLUWA, a óo sì máa rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú rẹ̀. Kí àwọn ọmọ yín má baà wí fún àwọn ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú pé, ‘Ẹ kò ní ìpín ninu nǹkan OLUWA.’

28. Èyí ni a fi ronú pé, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sí wa, tabi sí àwọn ọmọ ọmọ wa ní ọjọ́ iwájú, a óo lè wí pé, ẹ wo irú pẹpẹ OLUWA tí àwọn baba ńlá wá tẹ́, kì í ṣe pé wọ́n rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀, tabi ẹbọ mìíràn. Ẹ̀rí ni wọ́n fi ṣe láàrin àwa pẹlu yín.

29. A kò jẹ́ ṣe oríkunkun sí OLUWA tabi kí á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kí a má sì sìn ín mọ́ kí á wá tẹ́ pẹpẹ mìíràn fún ẹbọ sísun tabi ẹbọ alaafia tabi ẹbọ mìíràn, yàtọ̀ sí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa tí ó wà níwájú àgọ́ rẹ̀.”

30. Nígbà tí Finehasi alufaa, ati àwọn olórí ìjọ eniyan, ati àwọn olórí ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu wọn, gbọ́ ohun tí àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase wí, ọ̀rọ̀ náà dùn mọ́ wọn ninu.

31. Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa dá wọn lóhùn, ó ní, “Lónìí a mọ̀ pé OLUWA ń bẹ ní ààrin wa, nítorí pé ẹ kò hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí OLUWA, ẹ sì ti gba eniyan Israẹli lọ́wọ́ ìjìyà OLUWA.”

32. Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ní ilẹ̀ Gileadi; wọ́n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì jíṣẹ́ fún wọn.

Ka pipe ipin Joṣua 22