Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 21:4-19 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ilẹ̀ kinni tí wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọmọ Kohati. Nítorí náà, gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ ìran Aaroni alufaa gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Simeoni, ati ẹ̀yà Bẹnjamini.

5. Àwọn ọmọ Kohati yòókù sì gba ìlú mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Efuraimu, ẹ̀yà Dani, ati ìdajì ẹ̀yà Manase.

6. Àwọn ọmọ Geriṣoni gba ìlú mẹtala lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Isakari, ẹ̀yà Aṣeri, ẹ̀yà Nafutali, ati ìdajì ẹ̀yà Manase tí wọ́n wà ní Baṣani.

7. Àwọn ọmọ Merari gba ìlú mejila lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ẹ̀yà Sebuluni.

8. Àwọn ìlú náà ati pápá oko wọn ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ọmọ Lefi, lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣẹ́ gègé lé wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ láti ẹnu Mose.

9. Àwọn ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Simeoni fi àwọn ìlú náà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi,

10. tí wọ́n jẹ́ ọmọ Kohati, tíí ṣe ìran Aaroni, nítorí pé àwọn ni gègé kọ́kọ́ mú.

11. Àwọn ni wọ́n fún ní Kiriati Ariba tí wọ́n ń pè ní ìlú Heburoni lónìí, (Ariba yìí ni baba Anaki), ati àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ ní agbègbè olókè ti Juda.

12. Ṣugbọn àwọn oko tí wọ́n yí ìlú náà ká ati àwọn ìletò rẹ̀ ni wọ́n fi fún Kalebu ọmọ Jefune gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.

13. Àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, ni wọ́n fún ní ìlú Heburoni, tíí ṣe ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ati ìlú Libina pẹlu àwọn pápá ìdaran tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀.

14. Ati àwọn ìlú wọnyi pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Jatiri, Eṣitemoa,

15. Holoni, Debiri;

16. Aini, Juta, ati Beti Ṣemeṣi, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹsan-an ní ààrin ilẹ̀ àwọn ẹ̀yà mejeeji.

17. Láàrin ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú wọnyi pẹlu pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn: Gibeoni, Geba,

18. Anatoti ati Alimoni, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.

19. Àwọn ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, jẹ́ mẹtala pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.

Ka pipe ipin Joṣua 21