Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 21:39-45 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Heṣiboni, ati Jaseri pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.

40. Ìlú mejila ni wọ́n fún àwọn ìdílé yòókù ninu ẹ̀yà Lefi tí à ń pè ní Merari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

41. Gbogbo ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.

42. Olukuluku àwọn ìlú yìí ní pápá ìdaran tí ó yí i ká, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ìlú yòókù.

43. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà tán, wọ́n ń gbé ibẹ̀.

44. OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.

45. Ninu gbogbo ìlérí dáradára tí OLUWA ṣe fún ilé Israẹli kò sí èyí tí kò mú ṣẹ; gbogbo wọn patapata ni ó mú ṣẹ.

Ka pipe ipin Joṣua 21