Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 21:32-44 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili. Kedeṣi yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, wọ́n tún fún wọn ní Hamoti Dori, Katani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹta.

33. Ìlú mẹtala ati pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn ni ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Geriṣoni, gẹ́gẹ́ bi iye ìdílé wọn.

34. Ìdílé tí ó ṣẹ́kù ninu ẹ̀yà Lefi ni ìdílé Merari. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní: Jokineamu, Kata,

35. Dimna, Nahalali pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.

36. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni, wọ́n fún wọn ní: Beseri, Jahasi,

37. Kedemotu, ati Mefaati pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.

38. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní: Ramoti ní Gileadi. Ramoti yìí ni ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan. Wọ́n tún fún wọn ní Mahanaimu,

39. Heṣiboni, ati Jaseri pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.

40. Ìlú mejila ni wọ́n fún àwọn ìdílé yòókù ninu ẹ̀yà Lefi tí à ń pè ní Merari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

41. Gbogbo ìlú tí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ninu ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn.

42. Olukuluku àwọn ìlú yìí ní pápá ìdaran tí ó yí i ká, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ìlú yòókù.

43. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n gba ilẹ̀ náà tán, wọ́n ń gbé ibẹ̀.

44. OLUWA fún wọn ní ìsinmi ní gbogbo àyíká wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba wọn. Kò sì sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀tá wọn tí ó lè ṣẹgun wọn, nítorí pé OLUWA ti fi gbogbo àwọn ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Joṣua 21