Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 2:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.

2. Àwọn kan bá lọ sọ fún ọba Jẹriko pé, “Àwọn ọkunrin kan, lára àwọn ọmọ Israẹli, wá sí ibí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.”

3. Ọba Jẹriko bá ranṣẹ sí Rahabu ó ní, “Kó àwọn ọkunrin tí wọn dé sọ́dọ̀ rẹ jáde wá, nítorí pé wọ́n wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni.”

4. Ṣugbọn obinrin náà ti kó àwọn ọkunrin mejeeji pamọ́, ó dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni àwọn ọkunrin meji kan wá sọ́dọ̀ mi, ṣugbọn n kò mọ ibi tí wọn ti wá.

5. Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú lọ tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè ni wọ́n jáde lọ, n kò sì mọ ibi tí wọ́n lọ. Ẹ tètè máa lépa wọn lọ, ẹ óo bá wọn lọ́nà.”

6. Ṣugbọn ó ti kó wọn gun orí òrùlé rẹ̀, ó sì ti fi wọ́n pamọ́ sáàrin pòpórò igi ọ̀gbọ̀ tí ó tò jọ sibẹ.

7. Àwọn tí ọba rán bá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọkunrin náà lọ ní ọ̀nà odò Jọdani, títí dé ibi tí ọ̀nà ti rékọjá odò náà, bí àwọn tí ọba rán ti jáde ní ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi ìlú náà.

8. Kí àwọn amí meji náà tó sùn, Rahabu gun òrùlé lọ bá wọn, ó ní,

9. “Mo mọ̀ pé OLUWA ti fi ilẹ̀ yìí lé e yín lọ́wọ́, jìnnìjìnnì yín ti bò wá, ẹ̀rù yín sì ti ń ba gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí.

Ka pipe ipin Joṣua 2