Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 18:16-22 BIBELI MIMỌ (BM)

16. kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli.

17. Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà.

18. Ààlà náà kọjá lọ sí apá ìhà àríwá òkè Betaraba; láti ibẹ̀ ó lọ sí Araba.

19. Ó tún lọ sí apá ìhà àríwá òkè Beti Hogila, kí ó tó wá lọ sí apá etí Òkun Iyọ̀, níbi tí ó ti lọ fi orí sọ òpin odò Jọdani, ní ìhà gúsù. Ó jẹ́ ààlà ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini ní apá ìhà gúsù.

20. Odò Jọdani ni ààlà rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Èyí ni ilẹ̀ tí a pín fún ẹ̀yà Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé, pẹlu àwọn ààlà ilẹ̀ ìdílé kọ̀ọ̀kan.

21. Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi;

22. Betaraba, Semaraimu, Bẹtẹli;

Ka pipe ipin Joṣua 18