Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 18:14-28 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ó tún yípo lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, sí apá ìhà gúsù lọ sí ara àwọn òkè tí ó wà ní apá ìhà gúsù tí ó dojú kọ Beti Horoni, ó sì pin sí Kiriati Baali (tí wọ́n tún ń pè ní Kiriati Jearimu), ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Juda. Èyí ni apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ náà.

15. Ààlà ti apá ìhà gúsù ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ní àtiwọ ìlú Kiriati Jearimu lọ títí dé Efuroni, títí dé odò Nefitoa,

16. kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli.

17. Lẹ́yìn náà, ó yípo lọ sí apá àríwá, kí ó tó wa lọ sí Enṣemeṣi títí lọ dé Gelilotu tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, lẹ́yìn náà ó wá sí ìsàlẹ̀ ní ibi tí òkúta Bohani ọmọ Reubẹni wà.

18. Ààlà náà kọjá lọ sí apá ìhà àríwá òkè Betaraba; láti ibẹ̀ ó lọ sí Araba.

19. Ó tún lọ sí apá ìhà àríwá òkè Beti Hogila, kí ó tó wá lọ sí apá etí Òkun Iyọ̀, níbi tí ó ti lọ fi orí sọ òpin odò Jọdani, ní ìhà gúsù. Ó jẹ́ ààlà ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini ní apá ìhà gúsù.

20. Odò Jọdani ni ààlà rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Èyí ni ilẹ̀ tí a pín fún ẹ̀yà Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé, pẹlu àwọn ààlà ilẹ̀ ìdílé kọ̀ọ̀kan.

21. Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi;

22. Betaraba, Semaraimu, Bẹtẹli;

23. Afimu, Para, Ofira;

24. Kefariamoni, Ofini, ati Geba; gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila.

25. Gibeoni, Rama, Beeroti

26. Misipa, Kefira, Mosa;

27. Rekemu, Iripeeli, Tarala;

28. Sela, Haelefi, Jebusi (tí à ń pè ní Jerusalẹmu) Gibea, ati Kiriati Jearimu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrinla. Ilẹ̀ náà jẹ́ ìpín ti ẹ̀yà Bẹnjamini, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Ka pipe ipin Joṣua 18