Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 17:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.

2. Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.

3. Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkunrin rárá, àfi kìkì ọmọbinrin. Orúkọ wọn ni Mahila, Noa, Hogila, Milika, ati Tirisa.

4. Wọ́n tọ Eleasari, alufaa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati àwọn àgbààgbà lọ, wọ́n wí fún wọn pé, “OLUWA ti pàṣẹ fún Mose pé kí ó pín ilẹ̀ fún àwa náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti pín fún àwọn ìbátan wa, tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.” Nítorí náà bí OLUWA ti pa á láṣẹ, wọ́n pín ilẹ̀ fún àwọn náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pín fún àwọn ìbátan wọn tí wọ́n jẹ́ ọkunrin.

5. Ìdí nìyí tí ìpín mẹ́wàá fi kan Manase láìka Gileadi, ati Baṣani ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.

Ka pipe ipin Joṣua 17