Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 12:8-18 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.

9. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli;

10. Jerusalẹmu ati Heburoni,

11. Jarimutu ati Lakiṣi;

12. Egiloni ati Geseri,

13. Debiri ati Gederi;

14. Horima ati Aradi,

15. Libina ati Adulamu;

16. Makeda ati Bẹtẹli,

17. Tapua ati Heferi;

18. Afeki ati Laṣaroni,

Ka pipe ipin Joṣua 12