Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 12:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Lára ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni òkè Herimoni wà, ati ìlú Saleka, ati gbogbo Baṣani, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Geṣuri, ati ti àwọn ará Maakati ati ìdajì Gileadi títí dé ààlà ọba Sihoni ti ìlú Heṣiboni.

6. Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn.

7. Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, láti Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni títí dé òkè Halaki, ní apá Seiri. Joṣua pín ilẹ̀ wọn fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

8. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí òkè wà, ati àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní Araba, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aṣálẹ̀, ati ní Nẹgẹbu. Àwọn tí wọ́n ni ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ rí ni àwọn ará Hiti ati àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.

9. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli;

10. Jerusalẹmu ati Heburoni,

11. Jarimutu ati Lakiṣi;

12. Egiloni ati Geseri,

13. Debiri ati Gederi;

Ka pipe ipin Joṣua 12