Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 12:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi;

3. ati Araba, títí dé òkun Ṣinerotu ní apá ìlà oòrùn, ní ọ̀nà ìlú Beti Jeṣimotu, títí dé òkun Araba, (tí wọ́n tún ń pè ní Òkun Iyọ̀), títí lọ sí apá ìhà gúsù, títí dé ẹsẹ̀ òkè Pisiga.

4. Wọ́n ṣẹgun Ogu, ọba Baṣani náà. Ogu yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn tí ó kù ninu ìran Refaimu tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei.

5. Lára ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ ni òkè Herimoni wà, ati ìlú Saleka, ati gbogbo Baṣani, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Geṣuri, ati ti àwọn ará Maakati ati ìdajì Gileadi títí dé ààlà ọba Sihoni ti ìlú Heṣiboni.

6. Mose, iranṣẹ OLUWA ati àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba mejeeji yìí, ó sì pín ilẹ̀ wọn fún ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, ilẹ̀ náà sì di tiwọn.

Ka pipe ipin Joṣua 12