Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 10:30-43 BIBELI MIMỌ (BM)

30. OLUWA sì fi ìlú Libina ati ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n fi idà pa wọ́n, wọn kò ṣẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu wọn. Bí ó ti ṣe ọba Jẹriko, náà ló ṣe sí ọba ìlú náà.

31. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra láti Libina lọ sí Lakiṣi. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì bá a jagun.

32. OLUWA fi ìlú Lakiṣi lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, wọ́n sì gbà á ní ọjọ́ keji. Wọ́n fi idà pa gbogbo wọn patapata bí wọ́n ti ṣe pa àwọn ará Libina.

33. Horamu ọba Geseri wá láti ran àwọn ará ìlú Lakiṣi lọ́wọ́, Joṣua gbógun tì í, ó sì pa òun ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ láìku ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo.

34. Joṣua kúrò ní Lakiṣi, ó lọ sí Egiloni pẹlu gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dó ti Egiloni, wọ́n sì bá a jagun.

35. Wọ́n gba ìlú náà ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ patapata gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí àwọn ará Lakiṣi.

36. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Egiloni lọ sí Heburoni, wọ́n sì gbógun tì í.

37. Wọ́n gba ìlú Heburoni, wọ́n sì fi idà pa ọba ìlú náà ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ láìku ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí ìlú Egiloni tí wọn parun láìku ẹnìkan.

38. Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí Debiri, wọ́n sì gbógun tì í.

39. Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n mú ọba ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ìlú kéékèèké agbègbè rẹ̀ pẹlu. Wọ́n fi idà pa ọba wọn ati gbogbo àwọn ará ìlú náà. Gbogbo wọn ni wọ́n pa láìku ẹnìkan. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Heburoni, ati Libina ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe sí Debiri ati ọba rẹ̀.

40. Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un.

41. Joṣua ṣẹgun gbogbo wọn láti Kadeṣi Banea títí dé Gasa ati gbogbo agbègbè Goṣeni títí dé Gibeoni.

42. Joṣua mú gbogbo àwọn ọba wọnyi, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nítorí pé OLUWA Ọlọrun jà fún Israẹli.

43. Lẹ́yìn náà, Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pada sí àgọ́ wọn, ní Giligali.

Ka pipe ipin Joṣua 10