Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joẹli 2:9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọ́n ń gun odi ìlú,wọ́n ń sáré lórí odi.Wọ́n ń gun orí ilé wọlé,wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè.

10. Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn,ọ̀run sì ń wárìrì,oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn.

11. OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ,alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA!Ta ló lè faradà á?

12. OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii,pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn,

13. Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́,kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.”Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín,nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni.Kì í yára bínú,Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.

14. Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada,kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀,kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.

15. Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni,ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ.

16. Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.

17. Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

18. Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19. OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,ẹ óo ní ànítẹ́rùn.N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

20. N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òkú wọn yóo máa rùn;n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.

Ka pipe ipin Joẹli 2