Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 8:16-22 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀.

17. Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́,òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta.

18. Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀,kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí.

19. Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ,àwọn mìíràn óo dìde,wọn yóo sì gba ipò rẹ̀.

20. “Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́.

21. Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀.

22. Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ,ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”

Ka pipe ipin Jobu 8