Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 8:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà?Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi?

12. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́,yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko,láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀

13. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tíó gbàgbé Ọlọrun rí;ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun.

14. Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán,ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn.

15. Ó farati ilé rẹ̀,ṣugbọn kò le gbà á dúró.Ó dì í mú,ṣugbọn kò lè mú un dúró.

16. Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀.

17. Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́,òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta.

18. Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀,kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí.

19. Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ,àwọn mìíràn óo dìde,wọn yóo sì gba ipò rẹ̀.

20. “Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́.

21. Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀.

Ka pipe ipin Jobu 8