Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 8:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé,

2. “O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle?

3. Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po?Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada?

4. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni,ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

5. Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun,tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare;

6. tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́,dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́,yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ.

7. Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú.

8. “Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́,kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa.

9. Nítorí ọmọde ni wá,a kò mọ nǹkankan,ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji.

10. Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ,tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀,tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn.

Ka pipe ipin Jobu 8