Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 7:3-14 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù,ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́

4. Bí mo bá sùn lóru,n óo máa ronú pé,‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́,ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́.

5. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí,gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò.

6. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ,Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí.

7. “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́,ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́.

8. Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́;níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́.

9. Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí,kò ní pada mọ́.

10. Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́.

11. “Nítorí náà, n kò ní dákẹ́;n óo sọ ìrora ọkàn mi;n óo tú ìbànújẹ́ mi jáde.

12. Ṣé òkun ni mí ni, tabi erinmi,tí ẹ fi yan olùṣọ́ tì mí?

13. Nígbà tí mo wí pé,‘Ibùsùn mi yóo tù mí lára,ìjókòó mi yóo sì mú kí ara tù mí ninu ìráhùn mi’.

14. Nígbà náà ni ẹ̀yin tún wá fi àlá yín dẹ́rù bà mí,tí ẹ sì fi ìran pá mi láyà,

Ka pipe ipin Jobu 7