Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 7:16-21 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ayé sú mi,n kò ní wà láàyè títí lae.Ẹ fi mí sílẹ̀,nítorí ọjọ́ ayé mi dàbí èémí lásán.

17. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga,tí o sì fi ń náání rẹ̀;

18. tí ò ń bẹ̀ ẹ́ wò láràárọ̀,tí o sì ń dán an wò nígbà gbogbo?

19. Yóo ti pẹ́ tó kí ẹ tó mójú kúrò lára mi?Kí ẹ tó fi mí lọ́rùn sílẹ̀kí n rí ààyè dá itọ́ mì?

20. Bí mo bá ṣẹ̀, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ yín,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ́ mi?Kí ló dé tí ẹ fi dójú lé mi,tí mo di ẹrù lọ́rùn yín?

21. Kí ló dé tí ẹ kò lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì míkí ẹ sì fojú fo àìdára mi?Láìpẹ́ n óo lọ sinu ibojì.Ẹ óo wá mi,ṣugbọn n kò ní sí mọ́.”

Ka pipe ipin Jobu 7