Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 7:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ìgbésí ayé eniyan le koko,ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe.

2. Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiriati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀.

3. Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù,ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́

4. Bí mo bá sùn lóru,n óo máa ronú pé,‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́,ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún,títí ilẹ̀ yóo fi mọ́.

5. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí,gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò.

6. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ,Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí.

7. “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́,ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́.

8. Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́;níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́.

9. Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí,kò ní pada mọ́.

Ka pipe ipin Jobu 7