Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 6:4-12 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára,oró rẹ̀ sì mú mi.Ọlọrun kó ìpayà bá mi.

5. Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa kétí ó bá rí koríko jẹ?Àbí mààlúù a máa dúntí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀?

6. Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹláì fi iyọ̀ sí i?Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin?

7. Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ,Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi.

8. “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ,kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.

9. Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.

10. Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.

11. Agbára wo ni mo ní,tí mo fi lè tún máa wà láàyè?Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?

12. Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?

Ka pipe ipin Jobu 6