Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 6:10-24 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.

11. Agbára wo ni mo ní,tí mo fi lè tún máa wà láàyè?Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù?

12. Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí?Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ?

13. Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́,bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́.

14. “Ẹni tí ó bá kọ̀tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀kò ní ìbẹ̀rù Olodumare.

15. Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi,ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrátí ó yára kún,tí ó sì tún yára gbẹ,

16. tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn,tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ,

17. ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́,bí ilẹ̀ bá ti gbóná,wọn a sì gbẹ.

18. Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmíyà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiriwọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀.

19. Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá,àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí.

20. Ìrètí wọn di òfonítorí wọ́n ní ìdánilójú.Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀,ṣugbọn òfo ni wọ́n bá.

21. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii.Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín.

22. Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín?Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín,kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi?

23. Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá;tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára?

24. “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi,ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi;n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀.

Ka pipe ipin Jobu 6