1. Jobu bá dáhùn pé,
2. “Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi,tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n,
3. ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ.Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀.
4. Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára,oró rẹ̀ sì mú mi.Ọlọrun kó ìpayà bá mi.
5. Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa kétí ó bá rí koríko jẹ?Àbí mààlúù a máa dúntí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀?
6. Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹláì fi iyọ̀ sí i?Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin?
7. Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ,Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi.
8. “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ,kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́.
9. Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀,kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù.
10. Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi;n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora,nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́.