Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 5:13-24 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn;ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.

14. Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan,wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.

15. Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn,ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16. Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka,a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.

17. “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí,nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.

18. Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́,ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni.Ó ń pa ni lára,ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.

19. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà,bí ibi ń ṣubú lu ara wọn,kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.

20. Ní àkókò ìyàn,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú.Ní àkókò ogun,yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

21. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn,o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé.

22. Ninu ìparun ati ìyàn,o óo máa rẹ́rìn-ín,o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́.

23. O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ,àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ.

24. O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu.Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ,kò ní dín kan.

Ka pipe ipin Jobu 5