Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 42:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí náà, Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha, ati Sofari ará Naama lọ ṣe ohun tí OLUWA sọ fún wọn, OLUWA sì gbọ́ adura Jobu.

10. Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

11. Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan.

12. OLUWA bukun ìgbẹ̀yìn Jobu ju ti iṣaaju rẹ̀ lọ, ó ní ẹgbaaje (14,000) aguntan, ẹgbaata (6,000) ràkúnmí, ẹgbẹrun (1,000) àjàgà mààlúù ati ẹgbẹrun (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

13. Ó tún bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

14. Ó pe àkọ́bí obinrin ni Jemima, ekeji ni Kesaya, ẹkẹta ni Kereni Hapuki.

15. Kò sì sí ọmọbinrin tí ó lẹ́wà bí àwọn ọmọbinrin Jobu ní gbogbo ayé. Baba wọn sì fún wọn ní ogún láàrin àwọn arakunrin wọn.

16. Lẹ́yìn náà Jobu tún gbé ogoje (140) ọdún sí i láyé, ó rí àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin.

17. Ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́ kí ó tó kú.

Ka pipe ipin Jobu 42