Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 41:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Lọ fọwọ́ kàn án;kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!

9. “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.

10. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?Ta ló tó kò ó lójú?

11. Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.

12. “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.

13. Ta ló tó bó awọ rẹ̀,tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?

14. Ta ló tó ya ẹnu rẹ̀?Gbogbo eyín rẹ̀ ni ó kún fún ẹ̀rù.

15. Ẹ̀yìn rẹ̀ kún fún ìpẹ́ tí ó dàbí apata,a tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, wọ́n súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí bí èdìdì.

16. Àwọn ìpẹ́ náà lẹ̀ mọ́ ara wọn tímọ́tímọ́,tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè fẹ́ kọjá láàrin wọn.

Ka pipe ipin Jobu 41