Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 41:3-13 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ṣé yóo bẹ̀ ọ́,tabi kí ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?

4. Ṣé yóo bá ọ dá majẹmu,pé kí o fi òun ṣe iranṣẹ títí lae?

5. Ṣé o lè máa fi ṣeré bí ọmọ ẹyẹ,tabi kí o dè é lókùn fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ?

6. Ṣé àwọn oníṣòwò lè yọwó rẹ̀?Àbí wọ́n lè pín Lefiatani láàrin ara wọn?

7. Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀ gún ẹran ara rẹ̀,tabi kí o fi ẹ̀sín àwọn apẹja gún orí rẹ̀?

8. Lọ fọwọ́ kàn án;kí o wo irú ìjà tí yóo bá ọ jà;o kò sì ní dán irú rẹ̀ wò mọ́ lae!

9. “Ìrètí ẹni tí ó bá fẹ́ bá a jà yóo di òfo,nítorí ojora yóo mú un nígbà tí ó bá rí i.

10. Ta ló láyà láti lọ jí i níbi tí ó bá sùn sí?Ta ló tó kò ó lójú?

11. Ta ni mo gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ tí mo níláti dá a pada fún un?Kò sí olúwarẹ̀ ní gbogbo ayé.

12. “N kò ní yé sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ̀ rẹ̀,tabi nípa agbára rẹ̀ tabi dídára ìdúró rẹ̀.

13. Ta ló tó bó awọ rẹ̀,tabi kí ó fi nǹkan gún igbá ẹ̀yìn rẹ̀?

Ka pipe ipin Jobu 41