Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jobu 41:24-32 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,ó le ju ọlọ lọ.

25. Bí ó bá dìde, ẹ̀rù á ba àwọn alágbára,wọn á bì sẹ́yìn, wọn á ṣubú lé ara wọn lórí.

26. Bí idà tilẹ̀ bá a, kò ràn án,bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀kọ̀, ati ọfà, ati ẹ̀sín.

27. Irin kò yàtọ̀ sí koríko lójú rẹ̀,idẹ sì dàbí igi tí ó ti rà.

28. Bí wọn ta á lọ́fà, kò ní torí rẹ̀ sá,àwọn òkúta kànnàkànnà dàbí àgékù koríko lójú rẹ̀.

29. Kùmọ̀ dàbí koríko lára rẹ̀,a sì máa fi ẹni tí ó ju ọ̀kọ̀ lù ú rẹ́rìn-ín.

30. Ìpẹ́ ikùn rẹ̀ dàbí àpáàdì tí ó mú,wọn ń fa ilẹ̀ tútù ya bí ọkọ́.

31. Ó mú kí ibú hó bí omi inú ìkòkò,ó ṣe òkun bí ìkòkò òróró ìpara.

32. Bí ó bá ń rìn lọ, ipa ọ̀nà rẹ̀ a máa hàn lẹ́yìn rẹ̀,eniyan á rò pé òkun ń hó bí ọṣẹ ni.

Ka pipe ipin Jobu 41